Iyalẹnu
Naa |
The surprise |
Deesi gbé foonu ó si gbiyanju lati tun pè oníbàárà rẹ leekan si.
|
Daisy picked up the telephone and tried to get through to her client
again. |
Oníbàárà rẹ, ni Franki Baksini kan bayii, ti o ní ilé-ẹru nla kan
fun awọn ohun èlò-ina, kò tii sanwó fun ise ọjọ méjì ti oun se fun
un. |
Her client, a certain Frank Baccini, who had a warehouse of
electrical goods, had not paid for her two days' work. |
Deesi ti tiraka lati se awari ibi ti alailootọ ẹnikeji Ọgbẹni
Baksini n gbé bayii o sì n fi taratara reti sọwedowo rẹ.
|
Daisy had managed to discover where Mr. Baccini's dishonest partner
was now living and was anxiously expecting her cheque. |
Deesi ti bẹrẹ si ni rò o pé àfàìmọ ki Oníbàárà oun pẹlu naa
má jẹ alaisootọ. |
Daisy was beginning to think that her client was dishonest too. |
Ohun kan bi ẹni ti nnkan sú, dáhùn ni odikeji foonu, “Hẹlo, ki ni ẹ
fẹ?” |
A very bored "Hello, can I help you?" was the reply at the other
end. |
Ohùn ọdọbínrin kan tii se akọwe Franki Baksini ni. |
It was a young woman's voice, Frank Baccini's secretary. |
“Jọwọ, mo fẹ ba Ọgbẹni Baksini sọrọ,” |
"I'd like to speak to Mr. Baccini, please." |
“E má bínú o, Ọgbẹni Baksini kò si ni ilé.” |
"Sorry, Mr. Baccini is out of town." |
Deesi takú, o ni “amọ, igba wo ni yoo padà dé? |
"But when is he coming back?" insisted Daisy. |
“Emi kò mọ o” |
"I'm afraid I don't know." |
“N jẹ o le sọ fun un pé Deesi Hamitin pè e sori aago maa sì fẹ lati
ba a sọrọ ni kánkán.” |
"Will you tell him Daisy Hamilton telephoned and would like to talk
to him urgently." |
“Kò
burú, ó dara mo rò bẹẹ” ni gbogbo èsì kò-kàn-mi ti ó fun un. |
"Well - yes, I suppose so," was the completely unconcerned reply. |
Eyi ni ìpè sorí foonu ẹlẹkẹwaa ti Deesi maa ni laarin ọsẹ meji pelu
ọdọbínrin yii, sugbon Franki Baksini kò tii kàn si i paapaa. |
This was the tenth telephone conversation Daisy had had in two weeks
with this young woman, but Frank Baccini hadn't got in touch with
her yet. |
Inu
bi Deesi, o si pinnu lati lọ si ile-ẹru Ọgbẹni Baksini ki oun lè mọ
ti ó bá wà nibẹ. |
Daisy was furious and decided to go to Mr. Baccini's warehouse to
see if he was there. |
Nigbati
ó dé ibẹ, o kàn ilẹkun ọọfisi naa. |
When she arrived, she knocked on the office door. |
Pelu ohun ma-yọ-mi-lẹnu rẹ, Akọwe Baksini wi pe, “Wọle wá.” |
Mr. Baccini's secretary said in her monotonous voice: "Come in." |
“Mo ti pè sori aago ni aimoye igba – emi ni Deesi Hamitin.” |
"I've telephoned many times - my name is Daisy Hamilton." |
“Lootọ?
Tani o fẹ ba ni gbolohun?” ọdọbinrin naa beere lai tilẹ bojuwo
Deesi. |
"Really? Who did you want to speak to?" asked the young woman
without even glancing at Daisy. |
Deesi
fèsì pé, “Ọgbẹni
Baksini ni mo fẹ ba ni gbolohun. |
"I want to speak to Mr. Baccini," replied Daisy. |
Kódà
ó tilẹ ti mura ìjà sí i. |
She was becoming even more aggressive. |
Pelu
ohun ma-yọ-mi-lẹnu rẹ naa, o wi pe, “Ko si ni ibi o.” Ó sì tun n kà
iwe-irohin rẹ lọ. |
"I'm afraid he's not here," said the secretary in her usual
monotonous way and went on reading her magazine. |
Deesi
wi pelu ariwo pe, “Ó tó gẹẹ bayii”, ó sọ ilẹkun gbà-à. |
Daisy shouted "Enough is enough!" and banged the door closed. |
Ọkàn
Deesi kaarẹ lọpọlọpọ. |
Daisy felt rather depressed. |
“Mo
mọ ohun ti maa se,” Maa fẹsẹ kan duro ni isọ Luigi fun kétíya
ọlọgẹdẹ kan ti o dọsọ. |
"I know what I'll do," she thought, "I'll stop off at Luigi's for a
nice banana split." |
Deesi
fẹran lati maa jokoo si isọ kétíya Luigi, ki ó sì takurọsọ diẹ pẹlu
onisọ yii, ti ó jẹ ara Itali kan ti ki i se elérò buburu |
Daisy liked sitting in Luigi's ice-cream parlour and having a little
chat with the owner, a positive-thinking Italian. |
Bi
Deesi se mú òkè gùn lọ si ọọfisi rẹ, ọrọ ti o jẹ mọ awon ọmọ eniyan
kò dùn un mọ. |
As Daisy walked up the stairs to her office she felt a little less
sore about human beings. |
Bi Deesi se n paarọ bàtà rẹ lọwọ sí sálúbàtà, bẹẹ ni ẹnikan kàn
ilẹkun ti ó si wọle wá. |
Just as Daisy was changing her shoes to a more comfortable pair,
someone knocked on the door and walked in. |
Onisẹ kan ti ó wọ asọ isẹ toketilẹ ni |
It was a workman in overalls. |
“Omidan, ẹ jọwọ se ẹyin ni Omidan Deesi Hamitin? Nibo ni ki a gbé
awọn eleyii kalẹ sí?” ó n na ọwọ sí àpótí nla meji ti n bẹ ni
idasẹle àbágòkè. |
"Excuse me miss - are you Miss Daisy Hamilton? Where shall we put
these?" pointing to two large boxes on the landing. |
Bẹẹ
ni, emi ni Omidan Deesi Hamitin sugbọn ki ni awọn ohun ti ó wà ninu
awọn àpótí nibẹ yẹn?” |
"Yes, I am Daisy Hamilton but what have you got there - what's in
those boxes?" |
“Ẹrọ
amu-nnkan-tutú ni eyi ti o tobi yii, kekere sì jẹ ẹrọ ti n pò
ẹlẹrindodo. Awọn ti o yàn yii dara o, se o mọ, iru awọn ti ó dara jù
ni arọwọto ni yii.” |
"The big one is a fridge and the smaller one is a cappuccino-making
machine. You've chosen well, you know, these are the best makes
around." |
Deesi lọgun pe “Emi
ò sọ pe mo fẹ rà awọn yii o,” |
"I haven't ordered either of these," exclaimed Daisy. |
“Onisẹ
fi dandan mu u pe “Sugbọn orukọ rẹ ni n bẹ lori iwe ẹrù!” |
"But it's your name on the delivery note!" insisted the workman. |
“Gbogbo
owó ni ó ti wà ni àsanpé. Sá sọ ibi ti maa gbe wọn kalẹ si.” |
"It's all paid for - just tell me where to put them." |
Ó
kù diẹ ki Deesi kọ awọn ẹrù yii nigbati ó ri ti Franki Baksini pẹlu
n wọle bọ wá. |
Daisy was just about to refuse the goods when she saw Frank Baccini
coming in the door, too. |
“Omidan
Hamitin. Mo tọrọ aforijin pe mi ò kàn si ọ lati igba yii wá. |
"Miss Hamilton. I'm very sorry I haven't been in touch. |
“Mo
rò pe kò bi ọ ninu, mo ti sakiyesi pe o ò ni ẹrọ amu-nnkan-tutú ninu
ọọfisi rẹ ati…… ẹrọ ti n pò ẹlẹrindodo yii jẹ iru eyi ti kò wọpọ.
|
"I do hope you don't mind but I had noticed you didn't have a fridge
in your office and... this cappuccino-making machine is a little
specialty. |
“O,
tilẹ wò naa, sọwedowo rẹ ni yii fun isẹ ribiribi ti o se, pẹlu èènì
owó diẹ fun awọn ìnáwó pẹpẹpẹ rẹ” |
"Oh, by the way here is your cheque for the excellent work you did,
with a little extra for your expenses." |
Franki
Baksini ri pe ẹnu ya Deesi, ó fi kun ọrọ pe: |
Frank Baccini saw Daisy was astonished and added: |
“Mo
lero pe akọwe mi ti maa pe ọ? “Mo lọ irin ajo lati bi ọsẹ meloo diẹ
lati lọ gbadun pẹlu iyawo mi tuntun.” |
"My secretary did phone you, I hope? I've been away for a couple of
weeks on honeymoon." |
Deesi
yara sara rẹ giri, Rara, ko buru, kò pè mi – amọ ko si iyọnu,
Ọgbẹni Baksini. |
Daisy recovered herself, "Well, no, she didn't - but that's quite
all right Mr. Baccini!" |