A n Wá Lorna |
The search for Lorna
|
Deesi
Hamitin jẹ ọtẹlẹmuyẹ. |
Daisy Hamilton was a private detective. |
Ọmọ
ọgbọn ni i se ó tó ọdun meji sẹhin ti ó ti dà ọtẹlẹmuyẹ. |
She was thirty years old and had been a detective for the past two
years. |
Ni
araarọ, yoo kọri si ibi-isẹ rẹ lati se ireti ìpè lati ori ẹrọ
ibanisọrọ tabi ki ó sí ilẹkun fun awọn oníbàárà ti wọn nílò ọya rẹ. |
Every morning she went to her office to wait for phone calls or open
the door to clients needing her services. |
Deesi kò
ti i fi bẹẹ jẹ mimọ sibẹ sugbọn lẹẹkọọkan ni awọn eniyan maa n pè
sori aago lati ipasẹ ìpolówó ọja ti ó se si inu iwe irohin. |
Daisy wasn't very well known yet but occasionally people telephoned
her from the advertisement she had put in the local newspaper. |
Ni aarọ
ọjọ kan ni bi aago mọkanla ẹnikan kàn ilẹkun ọọfisi rẹ |
One morning at about eleven o'clock someone knocked on her office
door. |
Obinrin
sisanra kan ti ó wọ ọja onírun yí ọrun rẹ po ni. |
It was a fat lady who wore a fur around her neck. |
“Hẹlo,
bawo ni mo se lè jẹ iranwọ fun yin?” ni Deesi beere lọwọ rẹ. “Ẹ jọwọ
ẹ wá jókòó.” |
"Hello, can I help you?" Daisy asked the lady. "Please come and sit
down." |
“Bẹẹ
kúkú ni! Mo níló iranlọwọ ni yàjóyàjó. |
"Oh yes indeed! I need your help desperately. |
Lorna
eyi kekere mi ti poora o. Emi kò mọ nnkan ti mo fẹ se o.” |
Lorna, my little one has disappeared. I don't know what to do." |
Deesi fi
ife kọọfi kan lọ arabinrin naa ó sì àlàyé lẹkunrẹrẹ. |
Daisy offered the fat lady a cup of instant coffee and awaited the
details. |
Obinrin
titobi yii jokoo wọọ, ó sì gbé apamọwọ nla rẹ pupa kà orí tábìlì
Deesi. |
The fat lady sat down heavily and put her large red leather handbag
on Daisy's desk. |
“ Ẹ jọwọ
ẹ sọ bi gbogbo rẹ se jẹ fun mi – Iyaafin ….. ?” |
"Please tell me everything - Mrs. ...?" |
“Iyaafin
Edwina Họmfiris ni orukọ mi. Àyà mi n já kí wọn má lọ beere owó lọwọ
mi – Ẹmi mi kò balẹ pe wọn ti jí gbé lọ!” |
"Mrs. Edwina Humphries is my name. I am afraid they will ask me for
money - I'm afraid Lorna has been kidnapped!" |
Eyi buru
o, Iyaafin Họmfirisi. Se Ọgbẹni Họmfirisi pẹlu ni èró kan naa pe n
se ni wọn ti jí gbé lọ?” |
"That's terrible, Mrs. Humphries. Does Mr. Humphries, too, think
Lorna has been kidnapped?" |
Ọkọ mi
kò fihàn pe ó kàn oun rara boya wọn ti jí Lorna gbé lọ tabi bẹẹ kọ |
"My husband is not interested if Lorna has been kidnapped or not!" |
“Lootọ,
Iyaafin Họmfirisi? Amọ se ọkọ rẹ ni baba Lorna gan gan?
|
"Really, Mrs. Humphries? But is your husband Lorna's real father?" |
Iyaafin
Họmfirisi dahun pe “Emi kò mọ ohun ti o n sọ. A jọ parapọ rà Lorna
ni,” |
"I don't know what you mean. We bought Lorna together," replied Mrs.
Humphries. |
“Ẹ rà…..
Iyaafin Họmfirisi, eyi kò bófin mu, se o mọ.” |
"You bought ............Mrs. Humphries, that's illegal, you know." |
“Rara,
bẹẹ kọ, ni India kọ!” |
"No it isn't, not in India!" |
“Ẹ rà
Lorna ni India?” |
"You bought Lorna in India?" |
“Bẹẹ
kuku ni! Ki i si fi ẹgbẹ mi silẹ ni gbogbo ìgbà.,se o mọ.” |
"Yes indeed! And she always keeps me great company, you know." |
Iyaafin
Họmfirisi sí apamọwọ nla rẹ lati fà ìnujú pélébé jáde. |
Mrs. Humphries opened her huge leather bag to pull out a
handkerchief. |
Pẹlu
ibẹrubojo Lorna rì ti ẹda afàyàfà wọ jade lati inu apamọwọ yii. |
With horror Daisy saw a wiggling creature come out of that bag. |
Deesi
pariwo, “Iyaafin Họmfirisi – yán kini yẹn dànù kiakia! |
"Mrs. Humphries - move that away immediately!" screamed Daisy. |
Iyaafin
Họmfirisi wi pe“Kini, Lorna o – Mo ti rí ọ ni igbẹhin!” Inu apamọwọ
mi o sapamọ si – iwọ ọmọ ti ki i gbọran yii!” |
"What? Oh Lorna - I've found you at last!" said Mrs. Humphries."You
hid in my bag - you naughty girl!" |
“Iyaafin
Họmfirisi, Abi Lorna ni yii?” |
"Mrs. Humphries. This is Lorna?" |
Bẹẹ ni,
ejò ipadò Bengali wa. O seun o, onítèmi. Rara o, emi kò rò pe mo tun
nílò ọya rẹ mọ! |
"Yes, our Bengali swamp snake. Oh thank you my dear. No, I don't
think I need your services any longer!" |
Bi Deesi
ti n ti ilẹkun mọ Iyaafin Họmfirisi, o fi le ọkan rẹ lati kọ ọ sinu
ipolowo inu iwe irohin naa pe: wíwá ẹranko tabi ejò kò si lara isẹ
wa. |
As Daisy shut the door after Mrs. Humphries, she made a mental note
to write in the advertisement: no animals, no snakes. |